Ahọ́n
Ahọ́n | |
---|---|
Ahọ́n ọmọ ènìyàn | |
Details | |
Precursor | pharyngeal arches, lateral lingual swelling, tuberculum impar[1] |
System | Alimentary tract, gustatory system |
Artery | lingual, tonsillar branch, ascending pharyngeal |
Vein | Ìfọ̀ |
Nerve | Sensory Anterior two-thirds: Lingual (sensation) and chorda tympani (taste) Posterior one-third: Glossopharyngeal (IX) Motor Hypoglossal (XII), except palatoglossus muscle supplied by the pharyngeal plexus via vagus (X) |
Lymph | Deep cervical, submandibular, submental |
Identifiers | |
Latin | lingua |
TA | A05.1.04.001 |
FMA | 54640 |
Anatomical terminology |
Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara ìfọ̀ tí ó jẹ́ iṣan tí ó wà ní inú ẹnu ènìyàn tàbí ẹranko tí ó jẹ́ eléegun lẹ́yìn.
Iṣẹ́ tí ahọ́n ń ṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ahọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ya ara tí ọmọ ènìyàn ń lò fún ìbánisọ̀rọ̀, jíjẹ óúnjẹ, tí gbogbo ẹranko tókù sì ń lò ní ìlànà kan náà, yàtọ̀ sí ìbásisọ̀rọ̀ bí ti ọmọnìyàn. Ahọ́n wúlò púpọ̀ fún jíjẹ àti dídà óúnjẹ nínú àgọ́ ara nítorí àwọn èròjà amú óúnjẹ dà tí wọ́n ń pè ní (enzyme). Lára ahọ́n náà ni ìtọ́wò tí a fi ń mọ adùn àti kíkan. Ahọ́n tún sábà ma ń tutù látàrí èròjà tí ó ń pèsè itọ́ tí ó wà lára rẹ̀. Ahọ́n tún ma ń ṣe ìmọ́ tótó ẹnu nígba gbogbo, pàá pàá jùlọ eyín. [2] Kókó iṣẹ́ ahọ́n ni kí ó ṣètò ìró ohùn di ọ̀rọ̀ lára ènìyàn àti ohùn lásán lára àwọn ẹranko tókù.
Ọ̀nà tí ahọ́n pín sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ahọ́n ọmọnìyàn pín sí ọ̀nà méjì, àkọ́kọ́ ni Ìpín ibùsọ̀rọ̀, èyí wá ní ọwọ́ iwájú nígbà tí ìpín kejì jẹ́ tááná tí ó wà lọ́ ẹ̀yìn mọ́ ọ̀nà ọ̀fin. Apá ọ̀tún àti apá òsì ni iṣan tí ó nà tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó ń gbé ẹ̀jẹ̀ kiri gbogbo ara ahọ́n náà.
Àwọn Ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Àdàkọ:EmbryologyUNC
- ↑ Maton, Anthea; Hopkins, Jean; McLaughlin, Charles William; Johnson, Susan; Warner, Maryanna Quon; LaHart, David; Wright, Jill D. (1993). Human Biology and Health. Englewood Cliffs, New Jersey, USA: Prentice Hall. ISBN 0-13-981176-1. https://archive.org/details/humanbiologyheal00scho.