Leptospirosis
Leptospirosis | |
---|---|
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | A27. A27. |
ICD/CIM-9 | 100 100 |
OMIM | 607948 |
DiseasesDB | 7403 |
MedlinePlus | 001376 |
Leptospirosis (tí a tún mọ̀ sí ibà orí pápá,[1] àwọ̀ ìyeyè méku-méku,[2] àti ibà inú egungun ńlá tó lọ láti orúnkún sí kókósẹ̀[3] láàárín àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ mìíràn) jẹ́ àkóràn àrùn tí àwọn kòkòrò kékèké àìlèfojúrí corkscrew-shaped tí à ń pè ní Leptospira ń ṣe òkùnfà rẹ̀. Àmì àrùn lè má sí rárá, wọ́n lè wà níwọ̀nba, bíi orí-fífọ́, ẹran ara dídunni, àti ibà; wọ́n sì lè nira púpọ̀ ẹ̀dọ̀fóró tí nṣẹ̀jẹ̀ tàbí meningitis.[4][5] Bí àkóràn àrùn náà bá ṣe òkùnfà àyípadà àwọ̀ ẹni sí àwọ̀ ìyeyè, tó bá ní ìkùnà kídìnrín, tó sí ń da ẹ̀jẹ̀ lára, a ń pe èyí ní àìsàn Weil.[5] Bí ó bá ṣe òkùnfà ẹ̀jẹ̀ ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀fóró, a ń pè é ní àkópọ̀ àmì àrùn ẹ̀jẹ̀ ṣíṣe láti inú ẹ̀dọ̀fóró tó burú púpọ̀.[5]
Òkùnfà àti Ìwádìí àrùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oríṣi 13 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kòkòrò àrùn Leptospira ni ó lè fa àrùn náà lára ènìyàn.[6] Àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti ti ilé ni ó lè tan àrùn náà káàkiri.[5] Àwọn ẹranko tó wọ́pọ̀ jùlọ, tí wọ́n má a ń sábà tan àrùn náà kiri ni àwọn oríṣiríṣi èkúté àti asín.[7] A má a ń sábà tàn-án káàkiri nípasẹ̀ ìtọ̀ àwọn ẹranko tàbí nípasẹ̀ omi tàbí erùpẹ̀ tó ní ìtọ̀ ẹranko nínú, tí ó sì kan ojú egbò tó wà lára awọ ara, ojú, ẹnu, tàbí imú.[4][8] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìdàgbàsókè ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé, àrùn náà a má a sábà wáyé lára àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tálákà tí ń gbé ní àwọn ìlú náà.[5] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìdàgbàsókè, a má a sábà wáyé lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìta gbangba ní àwọn agbègbè tó má a ń lọ́wọ́rọ́ àti àwọn ibi tó má a ń tutù káàkiri àgbáyé.[4] Ìwádìí àrùn jẹ́ nípasẹ̀ wíwá àwọn àkóónú inú ẹ̀jẹ̀ tí ń gbógun ti kòkòrò àrùn, tí à ń pè ní antibodies àwọn èyítí ó lòdì sí kòkòrò àrùn náà tàbí nípa wíwá àwọn ohun tí a fi ń dá àwọn ohun ẹlẹ́ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan mọ̀, tí à ń pè ní DNA nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn kòkòrò àrùn náà.[9]
Ìdènà àrùn àti Ìtọ́jú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Akitiyan láti dènà àrùn náà jẹ́ nípa lílo ohun èlò ìdáàbòbò láti dènà fífarakanra nígbàtí ènìyàn bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹranko tó ti ní àrùn náà lára, fífọwọ́ ẹni lẹ́yìn irú ìfarakanra báyìí, àti nípa dídín àwọn èkúté àti asín kù ní àwọn agbègbè ibi tí ènìyàn ń gbé tàbí tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́.[4] Egbògi agbógun ti àkóràn doxycycline, bí a bá lòó láti fi dènà àkóràn àrùn láàárín àwọn arìnrìnàjò, kò ní ànfààní kan pàtó tó yanjú.[4] Àwọn àjẹsára fún àwọn ẹranko kan wà fún àwọn oríṣi Leptospira kan, èyí tó lè dín ewu àtànká àrùn náà sára àwọn ènìyàn kù.[4] Ìtọ́jú, bí ènìyàn bá ti kó àrùn náà, jẹ́ nípasẹ̀ àwọn egbògi agbógun ti àkóràn, gẹ́gẹ́ bíi: doxycycline, penicillin, tàbí ceftriaxone.[4] Àrùn Weil àti àkópọ̀ àmì àrùn ẹ̀jẹ̀ ṣíṣe láti inú ẹ̀dọ̀fóró tó burú púpọ̀ a má a fa ikú tó ju 10% àti 50% lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bí a bá tilẹ̀ ṣe ìtọ́jú pàápàá.[5]
Àtànká àti Ìṣàkóso àtànká àrùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A ti ṣe ìṣirò pé ó fẹ́rẹ̀ tó ènìyàn mílíọ̀nù méje sí mẹ́wàá tó má a ń ní àkóràn àrùn leptospirosis lọ́dún.[10] Iye ikú tí èyí ń fà kò tíì yé ni dáradára.[10] Àrùn náà wọ́pọ̀ jùlọ ní àwọn agbègbè ipa ọ̀nà òòrùn ní àgbáyé ṣùgbọ́n ó lè wáyé níbikíbi.[4] Àjàkálẹ̀ lè wáyé ní àdúgbò àwọn tálákà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń dàgbàsókè.[5] Ẹnití ó kọ́kọ́ ṣàpèjúwe àrùn náà ni Weil ní ọdún 1886 ní Germany.[4] Àwọn ẹranko tó ti ní àkóràn àrùn náà lè máṣe ní àmì àìsàn kankan rárá, wọ́n lè ní àmì àìsàn níwọ̀nba, tàbí kí wọ́n ní àmì àìsàn tó burú púpọ̀.[6] Àwọn àmì àìsàn lè yàtọ̀ sí ara wọn nítorí ara ẹranko tí wọ́n ti wáyé a má a yàtọ̀.[6] Làra àwọn ẹranko mìíràn Leptospira a máa gbé nínú ilé-ọmọ, èyí tó má a ń ṣe òkùnfà àtànká lásìkò ìbálópọ̀.[11]
Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Mosby's Medical Dictionary (9 ed.). Elsevier Health Sciences. 2013. p. 697. ISBN 9780323112581. http://books.google.ca/books?id=aW0zkZl0JgQC&pg=PA697.
- ↑ McKay, James E. (2001). Comprehensive health care for dogs. Minnetonka, MN.: Creative Pub. International. p. 97. ISBN 9781559717830.
- ↑ James, William D.; Berger, Timothy G.; et al. (2006). Andrews' Diseases of the Skin: clinical Dermatology. Saunders Elsevier. ISBN 0-7216-2921-0.:290
- ↑ 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 4.5 4.6 4.7 4.8 Slack, A (Jul 2010). "Leptospirosis.". Australian family physician 39 (7): 495–8. PMID 20628664.
- ↑ 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 5.5 5.6 McBride, AJ; Athanazio, DA; Reis, MG; Ko, AI (Oct 2005). "Leptospirosis". Current opinion in infectious diseases 18 (5): 376–86. doi:10.1097/01.qco.0000178824.05715.2c. PMID 16148523.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 "Leptospirosis" (PDF). The Center for Food Security and Public Health. October 2013. Retrieved 8 November 2014.
- ↑ Wasiński B, Dutkiewicz J (2013). "Leptospirosis—current risk factors connected with human activity and the environment". Ann Agric Environ Med 20 (2): 239–44. PMID 23772568. http://aaem.pl/fulltxt.php?ICID=1052323.
- ↑ "Leptospirosis (Infection)". Centers for Disease Control and Prevention. Retrieved 8 November 2014.
- ↑ Picardeau M (January 2013). "Diagnosis and epidemiology of leptospirosis". Médecine Et Maladies Infectieuses 43 (1): 1–9. doi:10.1016/j.medmal.2012.11.005. PMID 23337900.
- ↑ 10.0 10.1 "Leptospirosis". NHS. 07/11/2012. Archived from the original on 15 August 2015. Retrieved 14 March 2014. Check date values in:
|date=
(help) - ↑ Faine, Solly; Adler, Ben; Bolin, Carole (1999). "Clinical Leptospirosis in Animals". Leptospira and Leptospirosis (Revised 2nd ed.). Melbourne, Australia: MediSci. p. 113. ISBN 0 9586326 0 X.