Ilé-Ifẹ̀
Ilé-Ifẹ̀ Ifè Oòyè | |
---|---|
Fọ́nrán àwòrán èdè Ilé-Ifẹ̀ | |
Coordinates: 7°28′N 4°34′E / 7.467°N 4.567°ECoordinates: 7°28′N 4°34′E / 7.467°N 4.567°E | |
Country | Nigeria |
State | Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun |
Government | |
• Ọọ̀ni | Ọ̀jájá II |
• LGA Chairman, Ife Central | Ọ́ládosù Olúbísí |
• LGA Chairman, Ife North | Lánre Ògúnyímiká |
• LGA Chairman, Ife South | Timothy Fáyẹmí |
• LGA Chairman, Ife East | Tajudeen Lawal |
Area | |
• Total | 1,791 km2 (692 sq mi) |
Population (2006)[1] | |
• Total | 509,035 |
• Density | 280/km2 (740/sq mi) |
Climate | Aw |
Àpapọ̀ iye oníbùgbé |
---|
~ 755,260 |
Regions with significant populations |
Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun - 755,260 (2011) · Ife Central: 196,220 · Ife East: 221,340 · Ife South: 157,830 · Ife North: 179,870 |
Ifẹ̀ (Yorùbá: Ifẹ̀, tabi Ilé-Ifẹ̀) jẹ́ orírun gbogbo ọmọ Oòduà ní ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé-Ifẹ̀ wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[2] Ifẹ̀ sí ìlú Ìpínlẹ̀ Èkó je kilomita igba o le mejidinlogun (218) [3] tí àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ibẹ̀ lápapọ̀ jẹ́ 509,813 níye. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, Ilé-Ifẹ̀ ni wọ́n dá sílẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè nígbà tí ó pàṣẹ fún Ọbàtálá kí ó wá láti dá ayé kí ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṇ́ fẹ̀ láti ibẹ̀ lọ káàkiri àgbáyé; ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe Ilé-Ifẹ̀ ní Ifẹ̀ Oòyè, ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wáyé. Àmọ́, Ifẹ̀ yí ni Ọbàtálá pàdánù rẹ̀ sọ́wó Odùduwà Atẹ̀wọ̀nrọ̀, èyí ni ó fàá tí fàá ká ja ṣe wà láàrín àwọn méjèèjì.[4] Odùduwà ni ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba ní Ifẹ̀, ní èyí tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo náà sì di adarí àti olórí ìlú ní ẹlẹ́ka-ò-jẹ̀ka ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí káàkiri orílẹ̀ Yorùbá lóní.[5] Gẹ́gẹ́ bí a ti kàá nínú ìtàn, Ọọ̀ni àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ jẹ ní Ifẹ̀ ni ó jẹ́ ọmọ bíbí inú Odùduwà tí ó jẹ́ ọ̀kànlélógójì òrìṣà fúnra rẹ̀, nígbà tí Ọọ̀ni tí ó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyí jẹ́ Ọọ̀ni Adéyẹyè Ẹnìtàn Ògúnwùsì Ọ̀jájá Kejì(II) tí wọ́n jẹ ní ọdún 2015. Bákan náà ni Ilé-Ifẹ̀ ní ọ̀kànlélúgba òrìṣà tí wọ́n ma ń bọ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yípo ọdún.[6] [7]
Ilé-Ifè ìlú ńlá tí òkìkí rẹ̀ kàn jákè-jádò àgbáyé fún àwọn Iṣẹ́ ọnà wọn bíi ère orí Odùduwà àti àwọn ohun ọnà míràn tí wọ́n lààmì-laaka ní ǹkan bí ọdún 1200 àti 1400 A.D sẹ́yìn.[7]
Orin ìwúrí é-Ifẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ilé Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ tèmi
- Ilé Ifẹ̀, ìlú àwọn akọni
- Ibùgbé àwọn ènìyàn jàǹkàn
- Ibi ìfiṣolẹ̀ oríi Yoòbá
- Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí mo purọ́, ẹ sọ́ 5
- Ibẹ̀ nilé Àdìmúlà Ọọ̀ni Ifẹ̀
- Àjàláyé Ọlọ́fin Oòduà
- Ọ̀rànmíyàn ọba aláyé lu jára
- Mọrẹ̀mi òǹgbà tíí gbará àdúgbò
- Ẹ̀là Ìwòrì, ikọ̀ àjàlọ́run 10
- Òrìṣà bàmùtàtà bàmùtata tá a fi rọ́mọ ẹ̀dá padà
- Ilé Ifẹ̀, ìlú àwọn olùdá ayé
- Ifẹ̀, ìlụ́ àwọn àtọ̀runbọ̀
- Ifẹ̀ ni wọ́n gbé gbolúbi dúdú, funfun
- Ìyín lèèyàn òòṣà pàápàá forí rìn dé 15
- Njẹ́ ìwọ Ifẹ̀ oòyè dabọ̀, olórí ayé gbogbo
- Mo rántí bíyàà mi àgbà ṣe mọ́-ọn ń fi ọ́ kọrin
- Létí odò ẹ̀sìnmìrìn
- N kò rí ọ rí ká sọ pàtó
- Ṣùgbọ́n mo ríyà tó o jẹ lóríi wa 20
- Ojúù mi kò ṣàìtéjẹ̀ẹ̀ rẹ
- Ẹ̀jẹ̀ tó o ta sílẹ̀ fún wa
- Ẹ̀jẹ̀ tó tọwọ́ ìyà wá
- Ìyà tó tọwọ́ ìṣẹ́ wá
- Ìṣẹ́ tó tọwọ́ ẹ̀gbin rọ̀ọ́lẹ̀ 25
- Nígbà tọ́mọ tá a bí dé
- Wáá fọwọ́ ọrọ̀ júweelée baba ẹ̀
- Tí funfun dé wáá kó ọ lẹ́rú
- Tó kó ẹ tọmọ tòòṣà
- Ọ̀gọ̀rọ̀ òòṣàa wa la fi ṣàfẹ́ẹ̀rí 30
- Tá a firúnmọlẹ̀ ṣàwátì
- Òsùpá Ìjió ti lọ tèfètèfè
- Ilé-Ifẹ̀, ǹjẹ́ sọ fún mi, Ifẹ̀ oòyè dabọ̀
- Ṣ̣éwọ náà làwọn alára bátabàta ṣe báyìí ṣe?
- Tí wọ́n dójú tì ọ́, tí wọ́n kẹ́gbin bá
- ọ láa 35
- Ǹjẹ́ kí la ó ti sọ̀rọ̀ọ̀ wọn sí, ìwọ Ifẹ̀?
- Ká sáà fi wọ́n sílẹ̀ máa wòye
- Ká fọ̀rọ̀ fúnrúnmọlẹ̀
- Ká fáwọn igbámọlẹ̀ lọ́rọ̀ sọ
- Ká fọ̀rọ̀ ṣẹbọ ká fi ṣètùtù 40
- Kóhun rere tún lè padà sílé ifẹ̀
- Ení bá ní kẹ́bọ má dà
- Kó máa bẹ́bọ lọ réré ayé.
Àwọn ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
- ↑ "FEDERAL REPUBLIC OF NIGERIA : 2006 Population Census" (PDF). Archived from the original (PDF) on 5 March 2012. Retrieved 25 July 2016. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "The Descendants of Ife". dakingsman.com. Retrieved 17 July 2020.
- ↑ "World: Africa Arrests after Nigerian cult killings". BBC News. Monday July 12, 1999, Retrieved on October 31, 2011.
- ↑ Bascom, Yoruba, p. 10; Stride, Ifeka: "Peoples and Empires", p. 290.
- ↑ Akinjogbin, I. A. (Hg.): The Cradle of a Race: Ife from the Beginning to 1980, Lagos 1992 (The book also has chapters on the present religious situation in the town).
- ↑ Olupona, 201 Gods, 94.
- ↑ 7.0 7.1 Blier, Suzanne Preston (2012). "Art in Ancient Ife Birthplace of the Yoruba". African Arts 45 (4): 70–85. doi:10.1162/AFAR_a_00029. http://scholar.harvard.edu/files/blier/files/blier.pdf. Retrieved April 7, 2015.