Ice Prince
Ice Prince | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Panshak Henry Zamani |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Ice Prince |
Irú orin | Hip Hop, Afro Beat |
Occupation(s) | Singer, Rapper |
Years active | 2004–present |
Labels | Chocolate City |
Associated acts | M.I, eLDee, Wizkid, Skales, Brymo |
Website | Official website |
Panshak Henry Zamani, tí orúkọ orí ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Ice Prince ni a bí ní ọgbọ́n ọjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1986. Ó jẹ́ akọrin hip hop ọmọ Nàìjíríà tí ó ń kọ orin sílẹ̀ tí ó tún ṣeré orí ìtàgé. Òkìkí rẹ kàn nígbàtí ó gbé "Oleku", síta, orin náà jẹ́ ọ̀kan lára orin tí wọn ṣe àdàlú rẹ jùlọ ni orílè èdè Nàìjíríà.[1] Ó gba ipò kíní ní ọdún 2009 ní Hennessy Artistry Club Tour.[2][3]
Orin àkọ́kọ́ rẹ̀ ní yàrá ìtẹ orin síta tí ó pè ní gbogbo ènìyàn fẹ́ràn Ice Prince jáde ní ọdún 2011. Orin náà ní àtìlẹhìn àwọn orin mẹ́ta tí ó gbé jáde ni: "Oleku", "Superstar" àti "Juju". Ní ọdún 2013, Ice Prince gbé orin Fire of Zamani jáde gẹ́gẹ́ bí orin èkejì.
Àwo náà ní àwọn orin wonyi nínú: "Aboki", "More", "Gimme Dat" àti "I Swear". Ní ọjọ́ Kínní oṣù kéje ọdún 2015, wọ́n kéde Ice Prince gẹ́gẹ́ bíi igbákejì ààrẹ Chocolate City. Ó di oyè náà mú títí di ìgbà tí ó fi labeli náà sílè ni ọdún 2016.[4][5]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ice Prince's 'Oleku': Official video for one of Nigeria's most remixed hits". thisisafrica. Archived from the original on 2 December 2013. Retrieved 23 November 2013. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Hennessy Artistry". Hennessyartistry. Archived from the original on 21 October 2013. Retrieved 26 October 2013.
- ↑ "The Ice Prince was crowned: Photos and all the scoop from the Hennessy Artistry 2009 Finale". Bellanaija. 27 September 2009. Retrieved 26 October 2013.
- ↑ "M I Emerges As The New Chocolate City CEO". Naij.com. Archived from the original on 29 May 2016. Retrieved 17 September 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "MI Becomes Chocolate City CEO". Daily Times. Archived from the original on 15 October 2015. Retrieved 17 September 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)