Mwai Kibaki
Mwai Kibaki | |
---|---|
Mwai Kibaki, February 2012 | |
Aare ile Kenya | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 30 December 2002 | |
Alákóso Àgbà | Raila Odinga |
Vice President | Michael Wamalwa Kijana Moody Awori Kalonzo Musyoka |
Asíwájú | Daniel arap Moi |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 15 Oṣù Kọkànlá 1931 Gatuyaini, Kenya |
Aláìsí | 21 April 2022 |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | PNU |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Lucy Kibaki |
A bí Kìbákì ní ọjọ́kẹ̀ẹ̀ẹ́dógún oṣù kọ́kànlá ọdún (1931-2022) Orúkọ ìbatisi rẹ̀ ni Emilio Stanley ṣùgbọ́n kò pé tí ó fi orúkọ yìí sílẹ̀ tí ó ń jẹ́ orúko kìkúyí. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run kan ara Ítálì ni ó sà á lámì. Ọmọ ìjọ Àgùdà (Catholic) ni Kìbákì. History àti Political Science ni ó kà ní Màkéréré University ní Kampala, Uganda. Òun ni ó ṣ eipò kìíní nínú kíláàsì rẹ̀ nígbà tí ó jáde ní 1955. Ó fi ẹ̀kọ́-òfẹ̀ lọ London School of Economics níbi tí ó ti ka Public finance tí ó sì gboye B.Sc ní 1959. Ó pada sí makerere. Ó ṣe iṣẹ́ olùkọ́ díẹ̀ kí ó tó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ lọ máa ṣe òṣèlú. Ó gbé àpótí ó wọlé sí ilé aṣòfin. Wọ́n jọ dá ẹgbẹ́ Kenya African National Union (KANU) sílẹ̀ ni ní 1960 Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti wà nílé aṣòfin,wọ́n sọ ọ́ di Minister of Commerce and Industry. Nígbà tí Arap Moi di àrẹ lẹ́yìn ikú Jomo Kenyatta ní 1978, ó di igbá kejì àrẹ. Ní ọdún 1990, ó dá ẹgbẹ́ tirẹ̀ tí ó ń jẹ́ Democratic Party sílẹ̀ Ní ọdún 2002, ó di ààrẹ Kenya.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |